Işọ Òru |
Night Watch |
Deesi ti
tete ji ni aarọ ìgbà ibẹrẹ òjò yii toripe o n sisẹ lori ẹjọ kan ni
ileto kan ni itosi. |
Daisy had got up early that spring morning because she was working
on a case in the nearby town. |
O de ibi
isẹ rẹ pẹlu apamọwọ kan ni ọwọ rẹ ti nnkan ipanu n bẹ ninu rẹ, ni bi
i agogo mẹjọ ku isẹju marundinlogun o si n poungbẹ lati mu ife
kọfi kan |
She arrived at her office with a paper bag in her hand containing
fresh cream buns at a quarter to eight and was dying for a cup of
coffee. |
Bi o se
fi kọkọrọ si inu iho ilẹkun, obinrin kan ké sí i pé, “O wa ni sísí,
Deesi.” |
As she put the key in the lock, a woman’s voice called out, "It’s
open, Daisy." |
Pamu
agbalẹ ni. |
It was Pam, the cleaner. |
Pẹlu ẹrin
ni ẹnu rẹ, Deesi ni “Pamu, ounjẹ aarọ diẹ nkọ?” Lẹhin naa, o si se
akiyesi pe o daju pe, Pamu n sunkun. |
"How about some breakfast, Pam?" said Daisy with a smile and then
noticed Pam had obviously been crying. |
“Pamu,
kini o ba a sẹlẹ?” |
"Pam, whatever has happened? |
Wa
jokoo, ki o jẹ ounjẹ aarọ diẹ pẹlu mi |
Come on sit down and have some breakfast with me. |
“Dakun,
sọ fun mi nnkan ti o n jẹ o lọkan”? |
Please tell me what’s bothering you." |
Pamu jẹ
obinrin kan ti o jara mọ isẹ pẹlu ọmọ rẹ meji lati tọ |
Pam was a hard-working woman with two children to bring up. |
O n se
imọtoto gbogbo ile naa, eyi ti i se ọọfisi meje |
She did the cleaning for the whole building which meant seven
offices. |
“Jimu
tun ti n yọmilẹnu lori awọn ọmọ o. |
"Jim has been on to me again about the children. |
O mọ pe
kò lasẹ kankan lati maa ri wọn, kò si kuku kọ ibi ara si wọn rara,
ko tilẹ se bẹẹ ri |
You know he has no legal right to see them and he really couldn’t
care less about them, and never has." |
“Jẹ ki a
gbe àgé lé ina” |
"Let’s put the kettle on." |
Deesi
bẹrẹ si ni i pò kọfi ti o maa n tete yoro o si na bọnsi
kan si Pamu |
Daisy began preparing the instant coffee and offered Pam a bun, |
“Bayii,
kilode ti o kò bẹrẹ lati ibẹrẹ?” |
"Now, why don’t you start from the beginning?" |
Pamu n wò
bi ẹniti wahala ba o si n ba ọrọ rẹ lọ: |
Pam looked extremely troubled and went on: |
“Wo o,
nigbati a kọ ara wa silẹ kò tilẹ beere pe oun fẹ ri awọn ọmọ oun
rara |
"You see, when we got divorced he didn’t even ask to see his
children. |
Nisinsin
yii, kò ni owo lọwọ, ó n fi ara ni mi ki n le fun ni diẹ pẹlu ihalẹ
pe bi bẹẹ kọ, oun yoo gba awọn ọmọ kuro lowo mi.” |
Now he’s got no money, he’s trying to torture me into giving him
some with the threat that otherwise he’ll get the children away from
me." |
Deesi
fesi pẹlu arojinlẹ “Pamu, emi kò rò pe eyi yoo rọrun fun un lati se.
|
"I don’t think he can do that easily, Pam," Daisy reasoned. |
Pamu tẹwọ
gba bọnsi kan si. |
Pam accepted another bun. |
“Deesi
bẹẹ kọ, ki i se pẹlu irọrun, sugbọn o ní inu buruku gan an, o si ti
dúnkokò mọ mi pe oun yoo fi oju mi han eemọ.” |
"No Daisy, not easily, but he’s very vindictive and he’s threatened
to make my life a hell." |
“ Ko
buru, ki a si maa wo o na. |
"Well, we’ll just have to wait and see. |
Wo o, ti
o ba fẹ lo jagidi-jagan, ohun ti iwọ yoo se ko ju ki o pe awọn
ọlọpaa lo.” |
Look, if he gets violent all you have to do is call the police." |
“ Mo mo
Jim, ti n ko ba fun ni owo, dandan ni ki o mu oro rẹ sẹ.” |
"I know Jim, if I don’t give him money he’ll be as good as his
word." |
Lehin
ojo mẹta, Deesi gba ipe lori aago |
Three days later Daisy got a telephone call. |
“Deesi,
Pamu ni. Mo n yipo lo |
" Daisy, it’s Pam. I’m going round the bend. |
Jimu ti
n wa si tosi ile mi ni alaalẹ ni kete ti ile-ọtí ba ti palẹmọ tan, o
si maa n fẹ yọju wo ferese yara mi, o tun maa n ke ni ona ti o bani
lẹru. |
Jim’s been coming round to my house every night after the pubs close
trying to see through my bedroom window and making strange noises. |
O fẹ pin
mi lẹmii ki n le ba a gbà, ki n si le kó gbogbo owó naa ti o beere
fun un. |
He’s trying to get on my nerves so that I’ll give in and hand over
all the money he asks for. |
Emi kò
ti i fi oju ba orun lati bi ọjọ mẹta.” |
I haven’t slept for three days." |
“Se o ti
fi eyi tó awọn ọlọpaa leti?” |
" Have you informed the police about it?" |
“Jimu sọ
fun mi lori aago pe laipe pe, ti mo ba pe awọn ọlọpaa si oro yii,
oun yoo so wọn pe, emi ko mọ nnkan ti mo n se mọ, mo ti n se
wanran-wanran ati pe mo ti ni aarun ọpọlọ, ko si yẹ ki awọn ọmọ si
tun wa ni ikawọ mi mọ. |
"Jim telephoned me just now and said that if I call the police in,
he’ll tell them I’m imagining things and hysterical and mentally ill
and shouldn’t have his children in my custody. |
Kini
ohun ti mo le se bayii, Deesi? Ọkan mi ko balẹ mọ.” |
What am I going to do Daisy? I feel desperate." |
“ Pamu,
o dara, sọ nọmba ile rẹ fun mi emi yoo si wo nnkan ti mo le se si i.
|
"All right Pam, tell me your address and I’ll see what I can do." |
Deesi lọ
si Trends, sọọbu ti o ti maa n ra ẹrọ amohunmaworan,
redio ati kọmputa, o beere lati ba ẹni ti o ni sọọbu naa,
Ọgbeni Rainee sọrọ. |
Daisy went round to Trends, her local television, radio and
computer shop, and asked to speak to Mr. Ranjee, the owner of the
shop. |
Ọgbẹni
Rainee n jẹ o lero pe o le yá mi ni ẹro agbohun-gbaworan rẹ fun bi
ọjọ meloo kan?” |
"Mr. Ranjee, do you think you could lend me a camcorder for a couple
of days?" |
Deesi ti
se awari agbewiri ti o maa n ja iso naa ni olè ni bi osu diẹ sẹhin
|
Daisy had found the thief who was stealing from the shop a few
months’ ago |
Ogbeni
Rainee si n so ni igba gbogbo pe bi o ba ni ohunkohun lati lo, ki o
jowo beere fun un. |
and Mr. Ranjee had always said that if ever she needed something,
please to come and ask for it. |
“ Bẹẹ ni
o ri, Omidan Hamitin. O ni o fẹ eyi ti o le sisẹ ninu okunkun. |
"Of course, Miss Hamilton. You say you want one that works in the
dark. |
Mm – gba
eyi. Se o mọ ọ lo? Jẹ ki n fi han ọ.” |
Mm - take this. Do you know how to use it? Let me show you." |
Ọgbẹni
Rainee lò bi ọgbọn isẹju lati kọ Deesi ni awọn arekereke pẹẹpẹẹ diẹ
nipa ẹrọ agbohun-gbaworan naa. |
Mr. Ranjee spent the next half hour teaching Daisy some elementary
camcorder tricks. |
Deesi
pinnu lati lọ si ile Pamu ni bi aago mẹwaa alẹ ọjọ naa, o di ihamọra
pẹlu ẹrọ agbohun-gbaworan naa ati ideri tami-danu rẹ. |
Daisy decided to go around to Pam’s house at about ten that evening
armed with the camcorder and its rain-proof covering. |
O tun mu
fere ọdẹ kan lọwọ ninu apo rẹ ati ọpa Mars kan lati maa fi da
ara rẹ lara yá. |
She also had a whistle in her pocket and a Mars bar to while away
the time. |
Rara o!
ojo ti bẹrẹ si ni rọ,” Deesi kigbe mọ ararẹ. |
"Oh no! It’s beginning to rain," Daisy exclaimed to herself. |
Igbakigba ti ó ba ni isẹ lọwọ lati se ni oru, ni ọjọ maa n saaba rọ |
Whenever she had a job on at night it invariably rained. |
Ọlọrun ba
a se ni asiko yii, o mu aromiyo kan lọwọ o si da bo ara rẹ |
Fortunately, this time, she had brought a plastic mac and hood with
her. |
Ni iru
ọwọ oru bi eyi, awọn eniyan ki i pọ layika |
At that time of night there were few people around. |
Pamu ti
se alaye pe ile atijọ kekere kan ni oun n gbe ati pe yara oun wa ni
ọna ẹhin, ó kọju si ọgba |
Pam had explained that she lived in an old cottage, and that her
bedroom was round the back facing the garden. |
Nigbati
Deesi de, o lo si ọna ẹhinkule ile kekere naa, o mu odi kukuru naa
gun |
When Daisy arrived, she went to the back of the cottage, climbed
over the low fence |
O si ri
pe atibaba ẹru kan ti o ti wo lulẹ wa ni isalẹ ọgba naa |
and saw there was a tumble-down tool shed at the bottom of the
garden. |
“Ibi yii
ni maa sa pamọ si ki ẹhanna naa fi de. |
"That’s where I’ll hide and wait for that monster. |
“Kini ò
danwo ti o fi n wahala Pamu” Deesi n ro ninu ọkan rẹ. |
How dare he try to hurt dear Pam," thought Daisy. |
Lẹhin
igba diẹ ti o ti wa ninu atibaba-ẹru naa, o gbọ ti nnkan kan bọ lulẹ
bi i ikoko ododo ni ita |
Once inside the shed Daisy heard something like a flower-pot fall to
the ground outside |
O si ba
mọlẹ tori ki a ma ba a ri lati ibi ferese didọti kekere kan.
|
and crouched down so that she couldn’t be seen through the small
dirty window. |
O jọ bi
ibi ipade fun awọn olongbo ni, tori pe o gbọ ti awọn olongbo n ke,
mi-a-ou |
Apparently it was a meeting-place for cats, for she heard miaowing. |
“Dajudaju ti ọkọ atijọ Pamu ba tun maa pada wa se bi isẹ rẹ, mo ni
lati le awọn olongbo yii, ki wọn ma sẹruba a |
"Certainly if Pam’s ex-husband wants to repeat his previous
performance, I’d better get rid of those cats so he’s not scared
off." |
O fi
pẹlẹpẹlẹ si ilẹkun atibaba-ẹru naa, o si ju bata aloku kan ti o ri
ninu rẹ lu awon olongbo naa, lọgan ni wọn parẹ |
She opened the shed door warily and threw an old shoe she had found
inside at the cats, who hastily vanished. |
Ni
bayii, ohun gbogbo parọrọ lẹẹkan si |
Now everything was quiet again. |
Lẹhin
wakati meji, gbogbo ara wó Deesi, nitori otutu ati ọrinrin, o dide
soke kuro lori aga onipankẹrẹ ti o jokoo le. |
Two hours later Daisy, very stiff from the damp and cold, got up
from the ancient wicker chair she had been sitting on. |
“N ko
tun le farada mọ” Deesi n dasọ pẹlu irora |
"I can’t stand it much longer" she moaned to herself. |
Nigba naa
ni o dabi i pe o gbọ iro bata Wellington ti n tẹ irawe tutu
bọ sua-sua |
Then she thought she heard the noise of Wellington boots sloshing
through the damp foliage. |
Ẹnikan n
rakoro lọ si ibi ilẹ naa |
Someone was creeping towards the house. |
Apa n ro
Deesi nitori gbogbo akoko ti o palọlọ,ti ko fẹ mira o si ku diẹ ki
ẹrọ agbohun-gbaworan jabọ kuro lọwọ rẹ |
Deesi’s arms ached because of the enforced inaction and she nearly
dropped the camcorder. |
O yọ ẹsẹ
kuro ninu awon bata rẹ o si yo gele gba ẹnu ilẹkun àtíbàbà naa jade.
|
She stepped out of her shoes and slipped out of the partially-open
shed door. |
Ni asiko
yii gan an gan an ni ọkọ ayokẹlẹ kan rekọja pẹlu ina rẹ ti o tan
ran-ran-ran Deesi si le riran daradara |
At that very moment a car passed by with its lights fully on and
Daisy could see quite clearly: |
Ọkọ Pamu
tẹlẹ-rí n ti oju ferese yoju wò inu yara naa. |
Pam’s husband was spying into her bedroom window. |
Deesi se
ara kankan o si tan ẹrọ agbohun-gbaworan naa |
Daisy managed to act quickly and turned the camcorder on. |
Bayii,
ojo kan rọra n fọn diẹdiẹ ni |
It was only drizzling now. |
Ọkọ Pamu
bẹrẹ si ni ti oju ferese pariwo mọ iyawo rẹ tẹlẹ-rí o si n dunkoko
mọ ọ |
Pam’s husband began shouting through the window at his ex-wife and
threatening her. |
Deesi n
gba aworan naa silẹ pẹlu gbogbo ọrọ buruku ti n jade lenu rẹ |
Daisy was filming the scene and recording all the menacing words. |
Lojiji
erọ gbohun-gbaworan naa ke igbe odi kan |
Suddenly the camcorder made a strange whirring sound. |
Aya
Deesi ja. “Ki o ma jẹ pe ọja ẹrọ naa ti há o” |
"Maybe the tape’s blocked!" panicked Daisy. |
O tiraka
lati pa a sugbọn o tẹ itẹkutẹ, ariwo naa si lọ soke si |
She tried to turn it off but pushed the wrong button and the
whirring sound increased. |
Ni akoko
yii ni ọkọ Pamu atijo kobiara si i, o yipada pẹlu ibinu |
At this point Pam’s ex-husband became aware of it and turned round
furiously. |
O han si
pe ẹnikan ti n yọ oun wò, ó n bura kikan kikan |
He realized someone was watching him and swore profusely. |
Lẹhin
eyi o kọju si ọdọ Deesi bi i pe ki o digbolu |
Then he made towards Daisy as though to hit her. |
Ero ti o
kọkọ wa si ọkan Deesi ni ki o fi ara rẹ dabobo ẹrọ gbohun-gbaworan
naa, o kọ ẹhin si i, o si bẹrẹ si ni pariwo kikan-kikan
|
Daisy s first thought was to protect the camcorder with her body,
she turned her back on him and started yelling. |
Bi i pe
o ti n pariwo titi lailai ni |
It seemed to her that her yelling lasted an eternity. |
Lojiji ni
ina-ilewọ kan tan si awọn mejeeji |
Suddenly a strong torch light shone on both of them. |
“Ki ni o
n sẹlẹ nibẹ yẹn” |
"What’s going on here?" |
Obinrin
ọlọpa kan ni, o n wo togboju-togboju |
It was a police-woman, looking very determined. |
“Mo ri o
ti o n mu ogiri ogba yii gun” o n fi ina rẹ tokasi ọkunrin naa |
"I saw you climbing over the fence," indicating the man with
the light of her torch |
“Ẹyin
mejeeji, Ẹ maa bọ jẹjẹ” |
"Come quietly, both of you. |
“Mo n mu
yin fun irin régbe-régbe ati …… |
I'm arresting you for trespassing and ..." |
Ni akoko
yii gan an ni Pamu yọju lati oju ferese rẹ, o si i, o si bojuwo ita |
Just at this moment Pam appeared at her bedroom window, opened it
and looked out. |
“Ọlọpaa,
ọlọpaa, ọkunrin yii ni o n rin irin ti kò tọ, sugbọn ọrẹ mi ni
arabinrin naa” |
"Officer, officer. That man is certainly trespassing, but the young
lady is my friend." |
Lọgan ti
ẹnikeji obinrin ọlọpaa yii de ni wọn mu ọkọ Pamu tẹlẹ-rí lọ, wọn si
ni ki Deesi wọ ile naa lọ ki o lọ parada ki o si mu kọọbu tii
gbigbona kan. |
Pam’s ex-husband was taken away as soon as the constable’s colleague
appeared and Daisy was invited inside the cottage to clean up and
have a hot cup of cocoa. |
Deesi
ni, “ Ó daa o, ori lo kò mi yọ ọ” |
"Well, that was a bit of luck." said Daisy. |
“Pe mo
le fi ẹrọ gbohun-gbaworan ká a bi o se n yọju wo ferese rẹ ati bi
gbogbo ọrọ yii se se oju awọn ọlọpaa yii, |
"To be able to film him looking in your window at night and have the
whole scene witnessed by the police. |
“Emi ko
le ro pe Jim yoo tun yọ ọ lẹnu mọ!” |
I don’t think you’ll be having any more trouble from Jim!" |
Ọjọ
keji, Deesi de si ọọfisi rẹ ni bi i agogo mọkanla, o ba ikoko
ododo tutu nini kan ni ori tabili rẹ. |
Next morning at about eleven Daisy arrived in her office to find a
fresh bunch of flowers in a vase, on her desk. |
Lẹgbẹ rẹ
ni iwe pelebe kan wa, ti wọn fi pẹnsulu kọ nnkan si, |
Nearby was a little note written in pencil. |
“O seun
o Deesi, o seun lẹẹkan si. Pamu |
"Thanks Daisy, thanks again. Pam. |
AKIYESI:
Mo ti gbe ikoko eso pulọmu si inu apoti amú-un-tutù rẹ
|
P.S. I’ve put a pot of homemade greengage jam in your fridge." |